sentence
stringlengths 21
391
|
|---|
Àwọn ọlọ́jà ń ṣe ìwọ́de nílùú Ìbàdàn.
|
Adéyínká ti bá aṣẹ́wó méjì dòwòpọ̀, wọ́n sì ti gbáa mú
|
Bọ̀dé ti jáwé olúborí nínú ìdíje eré sísá tí a lọ.
|
Èyí ni bí àwọn agbébọn ṣe gbé òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ kan ní ìpínlẹ̀ Ògùn
|
Ìyá mi kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ sóké kí ilé má bàà dàrú
|
Bàbá mi ti wá san owó ilé-ìwé Bọ́lá àti Àdùnní.
|
Bíṣọ́bù Ìjọ Elétò Nàíjíríà ti jáde láyé.
|
Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ṣòfin ẹ̀wọ̀n gbére fún ẹnikẹ́ni tọ́ bá ṣe jìbìtì.
|
Sàláwù lùgbàdì kó àrùn kòrónà.
|
Ọkọ̀ òfurufú ni wọ́n fi gbé ọ̀daràn tó pa obìnrin kan lọ sí Èkó.
|
Oúnjẹ máa n fúnni lókun àti agbára.
|
Àwọn olè náà ti ra ìbọn titun.
|
Alága ìpínlẹ̀ Ayédáadé ti mórílè ilé ààrẹ tẹ́lẹ̀ láti lọ bẹ̀bẹ̀.
|
Ọmọ́tọ́lá Ẹkẹ́hìndé ti ṣe ayẹyẹ ìkómọjáde lọ́jọ́ kẹta oṣù kejì
|
Gómìnà Babajide pinu nǹkan mẹ́ta fún àwọn ọlọ́pàá ìpińlẹ̀ Èkó.
|
Òṣèré tíátà ọ̀hún ní àìsí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ṣe àkóbá fún ìtọ́jú òun
|
Ìjọba ìpínlẹ̀ Òǹdó kéde òfin kónílé-ó-gbélé ní fún àwọn ará ìlú.
|
Àlùfáà náà wo ọ̀pọ̀ sàn lọ́wọ́ àjàkálẹ̀ àrùn.
|
Mákindé ní òun ṣetán báyìí láti ró àwọn ọdẹ ìbílẹ̀ lágbára.
|
Inú bí mi sí fíìmù ayé tí wón máa ń ṣe.
|
Nàíjíríà wà nípò tó burú jùlọ nínú ìwà àjẹbánu.
|
Èèyàn márùn-ún di èrò ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn tí wọ́n sin wòlíì láàyè.
|
Adájọ́ ti dájọ́ ikú fún òsèré kan fún ẹ̀sùn apanìyàn.
|
Wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn gidi gan, wọ́n lè kú fún ara wọn.
|
Ìpàdé àláàfíà wáyé láàárín Olúọmọ Oṣòdì àti Kúnlé.
|
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọta ìbọn ológun ló ń wọnú ilé wọn lóru
|
Ìjọba ti kéde pé ojú irin Àgbàdo gbọdọ̀ se é rìn láìpẹ́.
|
Ìjọba àpapọ̀ yóò ṣí afárá lẹ́yìn ọdún.
|
Ọba Ọlájídé Ọláyọdé ni ọba àkọ́kọ́ tó jẹ́ ọ̀dọ́.
|
Adé àti Fúmmi kò jọra wọn, kí a má fi ewúrẹ́ wé ẹkùn
|
Obìnrin náà ní òun yóò san owó orí ọkọ òun tó bá wu òun
|
Olùkọ́ rẹ̀ ní òun ni atagìtá tó kéré jùlọ lágbàáyé.
|
Àgbà ọ̀jẹ̀ òṣèré náà kú lẹ́ni ọdún méjìdinlọ́gọ́run.
|
Dókítà ní ewu ń bẹ tórí táwọn akẹ́kọ̀ọ́ ba wọlé padà báyìí
|
Ìyá Àdìsá fẹ́ ma fi wá pawó lórí ayélujára.
|
Ilé ẹjọ́ pàṣẹ kí ìjọba àpapọ̀ san owó ìtanràn.
|
Ìwà burúkú Àdùnní kò dára rárá láwùjọ àti ní inú ilé.
|
Gàní ní dídákẹ́ òun lórí ìṣẹ̀lẹ̀ Ìgangan kìí ṣe ìwà òjó.
|
Inú ìjọba kò dùn sí ìṣẹ̀lẹ̀ òfò ẹ̀mí àti dúkìá tó wáyé.
|
Àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run tako ọ̀rọ̀ ọ̀gá àjọ tó ń gbógun ti òògùn olóró
|
Ìjọba yóò rí dájú pé irú rògbòdìyàn báyìí kò wáyé mọ
|
Òfin tuntun ló fa wàhálà láàárín àwọn ọ̀dọ́ àti àwọn aṣòfin.
|
Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ yóò ṣe ìwádìí ikú tó pa akẹ́kọ̀ọ́ ọ̀hún
|
Ìyábọ̀ Òjó àti Folúkẹ́ Dáramọ́lá ń bá màmá wọn sọ̀rọ̀ lórí fóònù
|
Bọ́lá fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí àyájọ́ ìjọba alágbádá.
|
Ètò iléra ṣe kókó fún gbogbo agbábọ̀ọ̀lù orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
|
Adéjọkẹ́ sọ pé ohun èlò tí òun nílò láti se oúnjẹ ni ẹran ìgbẹ́
|
Òfin láti tẹ àfipábánilòpọ̀ ní ọ̀dá gbọ́dọ̀ di mímúṣẹ.
|
Owó àti ìpalárà wà fún ẹni tó bá kọ̀ láti gbọ́ràn sí wa lẹ́nu.
|
Ó ti tó oṣù mẹ́ta tí bàbá Adérójú ti wà lẹ́wọ̀n
|
Ọmọba Fẹ́mi Oyéwùnmí tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Ládití ti jáde láyé.
|
Ọwọ́ tẹ olùṣọ́ tí ó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ oníjìbìtì ní Ifẹ̀.
|
Òfin ti mú ọkùnrin kan tí kò pa òfin kónílé-ó-gbélé mọ́.
|
Ó ti di ọgbọ̀n ènìyàn báyìí tó ti ní ààrùn jẹjẹrẹ ní Nàìjíríà.
|
Fẹ́mi Fálànà ní ẹjọ́ Ìgbòho ní Kútọnu kò le láti gbọ́
|
Ọkọ̀ àjàgbé agbépo kan tún dànù l'Ékòó.
|
Olúwo ti kánjú láti fẹ́ ìyàwó míìràn láì tíì kọ èyí tó fẹ́
|
Inú àmù ni Bọ́lá ti bu omi náà jáde wá fún mi láti mu.
|
Ọmọ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bámidélé ni àṣìta ìbọn ọdẹ àdùgbò kan ba.
|
Àjọ ìdáwò àṣekágbá gbẹ́sẹ̀ lé èsì ìdánwò àwọn akẹ́kọ̀ọ́.
|
Báwo ní ẹ̀mí mẹ́fà ṣe bọ́ lásìkò ìṣẹ̀lẹ̀ náà?
|
Alága ẹgbẹ́ òṣèlú ní ó wu àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tó darapọ̀ mọ́ wọn ni.
|
Mo jẹ́rìí pé Àdìsá á fi àgbà han àbúrò rẹ̀ kí n tó délé.
|
Ìjọba Èkó ti fòfin de ọjà títà àti títọọrọ báárà lójú títì
|
Wọ́n gé ẹsẹ̀ Adékúnlé nítorí pé ó ti ń jẹrà
|
Iye owó fọ́ọ̀mù ìdìbò abẹ́lẹ́ sípò gómìnà ti pọ̀ jù.
|
Bàbá olójú kan ni mo gbé ọjà mi fún lálẹ́ ọjọ́ yẹn
|
Ìjì àti òjò tó rọ̀ ní ìlú Ìlọrin ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́.
|
Àwọn ọba aláde kọ̀ọ̀kan ti ní kí Olúbàdàn yé fẹnu yẹpẹrẹ adé wọn.
|
Túndé ló fi ọlọ́pàá gbé Alága Ìgbìmọ̀ aláṣẹ ní Ìlọrin.
|
Àrá sán pa èèyàn mẹ́fà níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó náà.
|
Wo ìdí tí ìjọba ìpínlẹ́ Èkìtì ṣe fẹ́ kéde Kónílé-ó-gbélé tuntun.
|
Àwọn agbẹjórò ní ìpínlẹ̀ ọ̀ṣun ní àwọn yóó kọṣẹ́ sílẹ̀ fún oṣù díẹ̀ ná.
|
Ìmọ́tótó borí àrùn mọ́lẹ̀ bí ọyẹ ti ń borí oru.
|
Wọ́n ti ní ètò ìlera ti di dandan ṣáájú eré bọ́ọ̀lù kankan.
|
Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè yìí ti bèrè ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Olúbàdàn
|
Àjọ ètò ìlera gbọ́dọ̀ máa polongo ọ̀nà àti gbé ní àláàfíà.
|
Alága Káńsù náà ti kọ̀wé fi iṣẹ́ sílẹ̀.
|
Àlùfáà di èrò ẹ̀wọ̀n nítorí ó fi ipá bá ọmọ ìjọ lòpọ̀.
|
Olúgbọ́n ní ìjọba gbọdọ̀ sọ ẹni tó wà ní ìdí ọ̀rọ̀ náà.
|
Akọ́mọlédè àti Àṣà ti bẹ̀rẹ̀ lórí amóhùnmáwòrán wa
|
Kò sí omi mímu, kò sì tún sí omi láti fi wẹ̀ náà.
|
Níbi ìwọ́de tí wọn ń ṣe l‘Óṣogbo ni mo ti pàdé Ìyábọ̀ Ọbásanjọ́
|
Yẹmí lè lo odindi ọjọ́ kan láti máa bá èèyàn sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀
|
Inú mi dùn lati gbọ́ bí òwe Yoruba ṣe dùn lẹnu ọmọ yìí.
|
Mo rántí pé mo fẹ́ràn láti maa já mọ́tò gbà nínú ọjà
|
Ìpínlẹ̀ Èkó, Ọ̀yọ́, ati Èkìtì fi òfin de ìwà fífi màálù jẹ oko.
|
Ọmọ àlè ni àbí gbẹ̀yìn Àdìsá.
|
Ìkọlù sàfihàn pé ààrẹ ń gbìyànjú láti sọ orílẹ́èdè yìí di aworo.
|
Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó, Ọ̀ṣun, àti Ọ̀yọ́ ti ké gbàjarè nípa oun tó ṣẹlẹ̀.
|
Ṣèyí ni Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ báyìí.
|
Mo bèèrè pé irú èèyàn wo ni Fẹ́rànmi Fásùnlé jẹ́
|
Mo pàdé olólùfẹ́ mi nílé ẹlòmíràn lọ́jọ́ àbámẹ́ta
|
Ọwọ́ ọlọ́pàá ti tẹ àwọn afurasí ajínigbé méjì ní ìlú Èkó
|
Ìròyìn sọ pé ó ṣiṣẹ́ olórin rí ó sì ta àlòkù àṣọ.
|
Àwọn ọníṣẹ́ ọwọ́ wọ̀nyí ti gbowó iṣẹ́ wọn.
|
Onírúurú ìbòmú ló wá fún àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ tó fẹ́ wọlé padà.
|
Fọláshadé Tinúbú ti di Ìyálóde ìlú Iréwọlédé àti Owódé
|
Má fẹnu tẹ́mbẹ́lú èèyàn kan fún ohun tí wọ́n ṣe tàbí wọn kò ṣe.
|
Wọ́n ti mú mi gba abẹ́rẹ́ àjẹsára kí n má baà kó àrùn kòró
|
Subsets and Splits
No community queries yet
The top public SQL queries from the community will appear here once available.